Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 3:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn wọnyi ni ìdílé Aaroni ati ti Mose, nígbà tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai.

2. Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni lọkunrin nìwọ̀nyí: Nadabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Abihu, Eleasari ati Itamari.

3. Àwọn ni ó ta òróró sí lórí, láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ alufaa.

4. Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn.

5. OLUWA sọ fún Mose pé,

6. “Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un.

7. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.

8. Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.

9. Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

10. Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.”

Ka pipe ipin Nọmba 3