Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 28:27-31 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

28. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò: ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,

29. ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

30. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

31. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi pẹlu ẹbọ ohun mímu wọn, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ojoojumọ.

Ka pipe ipin Nọmba 28