Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 28:20-29 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,

21. ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

22. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

23. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ojoojumọ.

24. Báyìí ni ẹ óo ṣe rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA ní ojoojumọ fún ọjọ́ meje náà yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

25. Ní ọjọ́ keje ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

26. “Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún ìkórè, nígbà tí ẹ óo bá mú ẹbọ ohun jíjẹ ti ọkà titun wá fún OLUWA, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

27. Kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

28. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò: ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,

29. ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

Ka pipe ipin Nọmba 28