Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 28:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n.

12. Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.

13. Ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí jẹ́ ẹbọ sísun olóòórùn dídùn fún OLUWA.

14. Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.

15. Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ yìí, ẹ óo tún fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí OLUWA.

16. “Ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni Àjọ̀dún Ìrékọjá OLUWA.

Ka pipe ipin Nọmba 28