Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 28:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose

2. pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn.

3. “Ọrẹ tí wọn óo máa mú wá fún ẹbọ sísun tí ẹ óo máa rú sí OLUWA nìwọ̀nyí: ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ sísun ojoojumọ:

4. Ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àárọ̀ ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àṣáálẹ́,

5. pẹlu ìdámẹ́wàá ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró tí a gún pọ̀.

6. Èyí ni ẹbọ sísun ojoojumọ tí a ti fi ìlànà rẹ̀ lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

7. Ẹbọ ohun mímu rẹ̀ yóo máa jẹ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. O óo sì ta ọtí líle náà sílẹ̀ lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ bí ẹbọ sí OLUWA.

8. Ní ìrọ̀lẹ́, kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ bíi ti ẹbọ ohun jíjẹ òwúrọ̀ pẹlu ẹbọ ohun mímu rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA.

9. “Ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ fi ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ pẹlu idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu.

10. Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun yìí ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi pẹlu ẹbọ ojoojumọ ati ẹbọ ohun mímu.

11. “Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n.

12. Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.

Ka pipe ipin Nọmba 28