Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 27:19-23 BIBELI MIMỌ (BM)

19. kí o mú un wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan, kí o sì fún un ní àṣẹ lójú wọn.

20. Fún un ninu iṣẹ́ rẹ, kí àwọn ọmọ Israẹli lè tẹríba fún un.

21. Yóo máa gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Eleasari alufaa. Eleasari yóo sì máa lo Urimu ati Tumimu láti mọ ohun tí mo fẹ́. Ìtọ́ni Urimu ati Tumimu ni Eleasari yóo fi máa darí Joṣua ninu ohun gbogbo tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣe.”

22. Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un. Ó mú Joṣua wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan,

23. ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, ó sì fún un ní àṣẹ.

Ka pipe ipin Nọmba 27