Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 26:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.”

3. Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,

4. wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:

5. Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu,

6. ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi.

7. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730).

8. Palu bí Eliabu,

9. Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.

10. Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.

11. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú.

12. Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini;

Ka pipe ipin Nọmba 26