Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 26:19-33 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

20. Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera.

21. Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli.

22. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500).

23. Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua;

24. ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi.

25. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300).

26. Àwọn ọmọ Sebuluni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Seredi, ìdílé Eloni ati ìdílé Jaleeli.

27. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹta (60,500).

28. Àwọn ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: Manase ati Efuraimu.

29. Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi.

30. Àwọn ọmọ Gileadi nìwọ̀nyí: ìdílé Ieseri, ìdílé Heleki;

31. ìdílé Asirieli, ìdílé Ṣekemu;

32. ìdílé Ṣemida, ìdílé Heferi.

33. Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa.

Ka pipe ipin Nọmba 26