Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 26:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé,

2. “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.”

3. Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,

4. wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:

5. Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu,

6. ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi.

7. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730).

Ka pipe ipin Nọmba 26