Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 25:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè.

2. Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn.

3. Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn.

4. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.”

5. Mose sì wí fún àwọn onídàájọ́ Israẹli pé, “Olukuluku yín gbọdọ̀ pa àwọn eniyan rẹ̀ tí ó lọ sin oriṣa Baali tí ó wà ní Peori.”

6. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA.

Ka pipe ipin Nọmba 25