Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 24:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀,

2. ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,

3. ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní,“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú;

4. ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀.

5. Báwo ni àgọ́ rẹ ti dára tó ìwọ Jakọbu,ati ibùdó rẹ ìwọ Israẹli!

6. Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ,bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò.Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn,ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

7. Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀,omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀;àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu.Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ,ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga.

8. Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá,ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré.Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run,wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

Ka pipe ipin Nọmba 24