Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 23:7-19 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,kí o sì fi Israẹli ré.’

8. Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?

9. Mo rí wọn láti òkè gíga,mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

10. Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”

11. Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”

12. Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

13. Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”

14. Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”

16. OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ.

17. Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.

18. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Balaki, dìde, wá gbọ́,fetí sí mi, ọmọ Sipori;

19. Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada.Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe,bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 23