Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 23:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.”

2. Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3. Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.

4. Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”

5. OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un.

6. Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.

7. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,kí o sì fi Israẹli ré.’

8. Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?

9. Mo rí wọn láti òkè gíga,mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

10. Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”

11. Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”

12. Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

13. Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 23