Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú.