Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 20:10-14 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?”

11. Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu.

12. Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.”

13. Èyí ni omi Meriba, nítorí níbẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbolohun asọ̀ pẹlu OLUWA, tí OLUWA sì fi ara rẹ̀ hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun.

14. Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa.

Ka pipe ipin Nọmba 20