Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 20:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.

2. Kò sí omi fún àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n ṣe ibùdó sí, wọ́n sì kó ara wọn jọ sí Mose ati Aaroni.

3. Wọ́n ń kùn pé: “Ìbá sàn fún wa bí ó bá jẹ́ pé a ti kú nígbà tí àwọn arakunrin wa kú níwájú OLUWA.

4. Kí ló dé tí ẹ fi mú àwọn eniyan OLUWA wá sinu aṣálẹ̀ yìí? Ṣé kí àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú ni?

5. Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.”

6. Mose ati Aaroni kúrò níwájú àwọn eniyan náà, wọ́n lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, wọ́n dojúbolẹ̀, ògo OLUWA sì farahàn.

7. OLUWA sọ fún Mose pé,

8. “Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.”

9. Mose lọ mú ọ̀pá náà níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

10. Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?”

11. Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu.

12. Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 20