Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 2:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:

2. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká.

3. Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn.

4. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).

5. Kí ẹ̀yà Isakari pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Juda; Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí wọn.

6. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400).

7. Kí ẹ̀yà Sebuluni pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Isakari. Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí wọn.

8. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400).

9. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Juda jẹ́ ẹgbaa mẹtalelaadọrun-un ó lé irinwo (186,400). Àwọn ni yóo máa ṣáájú nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn.

10. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn.

11. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).

Ka pipe ipin Nọmba 2