Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 19:20-22 BIBELI MIMỌ (BM)

20. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kò sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, yóo jẹ́ aláìmọ́ sibẹ nítorí pé a kò tíì da omi ìwẹ̀nùmọ́ sí i lára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

21. Ẹ gbọdọ̀ pa ìlànà yìí mọ́ láti ìrandíran. Ẹni tí ó bá wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà sí aláìmọ́ lára gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan omi náà yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

22. Ohunkohun tí aláìmọ́ bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fọwọ́ kan ohun tí aláìmọ́ náà bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”

Ka pipe ipin Nọmba 19