Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 19:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

2. “Ìlànà tí èmi OLUWA fi lélẹ̀ nìyí: Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù pupa kan wá. Kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n kankan, wọn kò sì gbọdọ̀ tíì fi ṣiṣẹ́ rí.

3. O óo fún Eleasari alufaa, yóo mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, wọn óo sì pa á níbẹ̀ níṣojú rẹ̀.

4. Eleasari yóo gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn sí apá ìhà Àgọ́ Àjọ ní ìgbà meje.

5. Kí wọ́n sun ìyókù mààlúù náà: awọ rẹ̀ ati ẹran ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ati ìgbẹ́ rẹ̀; kí wọ́n sun gbogbo rẹ̀ níwájú alufaa.

6. Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà.

7. Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

8. Ẹni tí ó sun mààlúù náà gbọdọ̀ wẹ̀ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

9. Ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo kó eérú mààlúù náà jọ sí ibìkan tí ó mọ́ lẹ́yìn ibùdó. Eérú náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóo máa lò fún omi ìwẹ̀nùmọ́, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

10. Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae.

Ka pipe ipin Nọmba 19