Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 17:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nígbà tí ó wọ inú Àgọ́ Ẹ̀rí ní ọjọ́ keji, ó rí i pé ọ̀pá Aaroni tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi ti rúwé, ó ti tanná, ó ti so èso alimọndi, èso náà sì ti pọ̀.

9. Mose kó àwọn ọ̀pá náà jáde kúrò níwájú OLUWA, ó kó wọn wá siwaju àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn wò wọ́n, olukuluku àwọn olórí sì mú ọ̀pá tirẹ̀.

10. OLUWA sọ fún Mose, pé, “Dá ọ̀pá Aaroni pada siwaju Àpótí Ẹ̀rí, kí ó lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ Israẹli, kí wọ́n sì lè dẹ́kun kíkùn tí wọn ń kùn sí mi, kí wọ́n má baà kú.”

11. Mose sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

12. Àwọn ọmọ Israẹli bá sọ fún Mose pé, “A gbé! Gbogbo wa ni a óo ṣègbé.

13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yóo kú, ṣé gbogbo wa ni a óo ṣègbé ni?”

Ka pipe ipin Nọmba 17