Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 17:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ọ̀pá ẹni tí mo bá yàn yóo rúwé; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí ọ.”

6. Mose sọ èyí fún àwọn ọmọ Israẹli. Olórí àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan mú ọ̀pá wọn wá fún Mose, gbogbo rẹ̀ jẹ́ mejila, ọ̀pá Aaroni sì wà ninu wọn.

7. Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá náà siwaju OLUWA ninu Àgọ́ Ẹ̀rí.

Ka pipe ipin Nọmba 17