Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 16:25-40 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Mose bá dìde pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Datani ati Abiramu.

26. Ó sì sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn ọkunrin burúkú wọnyi, kí ẹ má sì fọwọ́ kan nǹkankan tí ó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má baà pín ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

27. Àwọn eniyan náà bá kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu.Datani ati Abiramu pẹlu aya ati àwọn ọmọ wọn jáde wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.

28. Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Nisinsinyii ni ẹ óo mọ̀ pé èmi kọ́ ni mo yan ara mi ṣugbọn OLUWA ni ó rán mi láti ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe.

29. Bí àwọn ọkunrin wọnyi bá kú ikú tí kò mú ìbẹ̀rù lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, a jẹ́ wí pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán mi.

30. Ṣugbọn bí OLUWA bá ṣe ohun tí etí kò gbọ́ rí, tí ilẹ̀ bá yanu tí ó gbé wọn mì pẹlu àwọn eniyan wọn ati àwọn ohun ìní wọn, tí wọn sì bọ́ sinu ibojì láàyè, ẹ óo mọ̀ pé wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀.”

31. Ní kété tí Mose parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé lórí là sí meji,

32. ó yanu, ó sì gbé wọn mì, ati àwọn ati ìdílé wọn, ati ohun ìní wọn. Ilẹ̀ sì gbé Kora mì pẹlu àwọn eniyan rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní wọn.

33. Gbogbo wọn, ati ohun ìní wọn, ati àwọn eniyan wọn, lọ sí ipò òkú láàyè, ilẹ̀ panudé, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ eniyan Israẹli.

34. Àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ sì sálọ nígbà tí wọn gbọ́ igbe wọn. Wọ́n bẹ̀rù kí ilẹ̀ má baà gbé àwọn náà mì.

35. OLUWA sì rán iná láti run àwọn aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọn mú àwo turari wá siwaju Àgọ́ Àjọ.

36. OLUWA sọ fún Mose pé,

37. “Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni, alufaa pé kí ó kó àwọn àwo turari wọ̀n-ọn-nì kúrò láàrin àjókù àwọn eniyan náà. Kí ó sì da iná inú wọn káàkiri jìnnà jìnnà nítorí àwọn àwo turari náà jẹ́ mímọ́.

38. Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

39. Eleasari bá kó àwọn àwo turari náà tí àwọn tí ó jóná fi rú ẹbọ, ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ.

40. Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.

Ka pipe ipin Nọmba 16