Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 15:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ;

5. ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu, pẹlu ẹbọ sísun tabi ẹbọ ọ̀dọ́ aguntan kan.

6. Fún ẹbọ àgbò, yóo wá ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá,

7. pẹlu ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu; yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA.

8. Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA,

9. ẹ óo mú ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá,

10. pẹlu ìdajì òṣùnwọ̀n hini ọtí waini kan, fún ẹbọ ohun mímu, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun. Yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA.

11. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe pẹlu akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan tabi àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọ̀dọ́ àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọmọ aguntan kọ̀ọ̀kan.

Ka pipe ipin Nọmba 15