Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 13:24-33 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Wọ́n sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣikolu, nítorí ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti gé ìtì èso àjàrà.

25. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wo ilẹ̀ náà fún ogoji ọjọ́, àwọn amí náà pada.

26. Wọn tọ Mose, Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli lọ ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Parani. Wọ́n sọ gbogbo ohun tí ojú wọn rí, wọ́n sì fi èso tí wọ́n mú wá hàn wọ́n.

27. Wọ́n sọ fún Mose pé, “A ti wo ilẹ̀ tí ẹ rán wa lọ wò, a sì rí i pé ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati fún oyin ni. Ó lẹ́tù lójú lọpọlọpọ; èso inú rẹ̀ nìwọ̀nyí.

28. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ń gbé inú rẹ̀ lágbára, ìlú ńláńlá tí wọ́n sì mọ odi yíká ni ìlú wọn. Ohun tí ó wá burú ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, a rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀.

29. Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.”

30. Ṣugbọn Kalebu pa àwọn eniyan náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á lọ nisinsinyii láti gba ilẹ̀ náà, nítorí a lágbára tó láti borí àwọn eniyan náà.”

31. Àwọn amí yòókù ní, “Rárá o! A kò lágbára tó láti gbógun ti àwọn eniyan náà, wọ́n lágbára jù wá lọ.”

32. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ wò. Wọ́n ní, “Ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn eniyan inú rẹ̀ ni ilẹ̀ náà, gbogbo àwọn tí a rí níbẹ̀ ṣígbọnlẹ̀.

33. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀, bíi tata ni a rí níwájú wọn.”

Ka pipe ipin Nọmba 13