Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 13:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ó rán Seturu, ọmọ Mikaeli;

14. láti inú ẹ̀yà Nafutali, ó rán Nahibi ọmọ Fofisi;

15. láti inú ẹ̀yà Gadi, ó rán Geueli ọmọ Maki.

16. Orúkọ àwọn ọkunrin tí Mose rán láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà nìyí. Mose sì yí orúkọ Hoṣea ọmọ Nuni pada sí Joṣua.

17. Mose rán wọn láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. Kí wọ́n tó lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà ìhà àríwá, kí ẹ tọ̀ ọ́ lọ sí ìhà gúsù ilẹ̀ Kenaani, kí ẹ wá lọ sí àwọn orí òkè.

18. Ẹ wo irú ilẹ̀ tí ilẹ̀ Kenaani jẹ́, àwọn eniyan mélòó ló ń gbé ibẹ̀ ati pé báwo ni wọ́n ṣe lágbára sí.

19. Ẹ ṣe akiyesi bóyá ilẹ̀ náà dára tabi kò dára, ati pé bóyá àwọn eniyan ibẹ̀ ń gbé inú àgọ́ ninu ìlú tí ó tẹ́jú tabi ìlú olódi ni ìlú wọn.

20. Ẹ wò bóyá ilẹ̀ náà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú, ẹ wò ó bóyá igi wà níbẹ̀ tabi kò sí. Ẹ múra gírí kí ẹ sì mú ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀.” (Àkókò náà sì jẹ́ àkókò àkọ́so àjàrà.)

21. Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati.

22. Wọ́n gba ìhà gúsù gòkè lọ sí Heburoni, níbi tí àwọn ẹ̀yà Ahimani, ati ti Ṣeṣai ati ti Talimai, àwọn òmìrán ọmọ Anaki ń gbé. (A ti tẹ Heburoni dó ní ọdún meje ṣáájú Soani ní ilẹ̀ Ijipti.)

23. Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣikolu, wọn gé ṣiiri àjàrà kan tí ó ní èso. Ṣiiri àjàrà yìí tóbi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn meji ni wọ́n fi ọ̀pá gbé e. Wọ́n sì mú èso pomegiranate ati èso ọ̀pọ̀tọ́ wá pẹlu.

24. Wọ́n sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣikolu, nítorí ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti gé ìtì èso àjàrà.

25. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wo ilẹ̀ náà fún ogoji ọjọ́, àwọn amí náà pada.

Ka pipe ipin Nọmba 13