Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 11:5-16 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki.

6. Ṣugbọn nisinsinyii, a kò lókun ninu mọ́, kò sí ohun tí a rí jẹ bíkòṣe mana yìí nìkan lojoojumọ.”

7. Mana náà sì dàbí èso korianda, tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí kóró òkúta bideliumi.

8. Àwọn eniyan náà a máa lọ kó wọn láàárọ̀, wọn á lọ̀ ọ́ tabi kí wọn gún un lódó láti fi ṣe ìyẹ̀fun. Wọn á sè é ninu ìkòkò, wọn á fi ṣe bíi àkàrà, adùn rẹ̀ sì dàbí ti àkàrà dídùn tí a fi òróró olifi dín.

9. Òròòru ni mana náà máa ń bọ́ nígbà tí ìrì bá ń sẹ̀ ní ibùdó.

10. Mose gbọ́ bí àwọn eniyan náà ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ wọn, olukuluku pẹlu àwọn ará ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Mose, ibinu OLUWA sì ru sí àwọn eniyan náà.

11. Mose bá wí fún OLUWA pé, “Kí ló dé tí o ṣe mí báyìí? Kí ló dé tí n kò rí ojurere rẹ, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn eniyan wọnyi rù mí?

12. Ṣé èmi ni mo lóyún wọn ni, àbí èmi ni mo bí wọn, tí o fi sọ fún mi pé kí n gbé wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn.

13. Níbo ni kí n ti rí ẹran tí yóo tó fún àwọn eniyan wọnyi? Wò ó! Wọ́n ń sọkún níwájú mi; wọ́n ń wí pé kí n fún àwọn ní ẹran jẹ.

14. Èmi nìkan kò lè ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi; ẹrù náà wúwo jù fún mi.

15. Bí ó bá jẹ́ pé bí o óo ti ṣe mí nìyí, mo bẹ̀ ọ́, kúkú pa mí bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, kí n má baà kan àbùkù.”

16. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Yan aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli mọ̀ ní olórí, kí o sì mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí wọ́n dúró pẹlu rẹ níbẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 11