Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 11:23-35 BIBELI MIMỌ (BM)

23. OLUWA dá Mose lóhùn, ó ní, “Ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún èmi OLUWA láti ṣe bí? O óo rí i bóyá ohun tí mo sọ fún ọ yóo ṣẹ, tabi kò ní ṣẹ.”

24. Mose jáde, ó lọ sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli; ó sì mú àwọn aadọrin olórí náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

25. OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà.

26. Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

27. Ọmọkunrin kan sáré wá sọ fún Mose pé Elidadi ati Medadi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

28. Nígbà náà ni Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọ̀kan ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wí fún Mose pé, “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.”

29. Mose dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń jowú nítorí mi? Inú mi ìbá dùn bí OLUWA bá lè fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.”

30. Lẹ́yìn náà Mose ati àwọn aadọrin olórí náà pada sí ibùdó.

31. OLUWA sì rán ìjì ńlá jáde, ó kó àwọn ẹyẹ kéékèèké kan wá láti etí òkun, wọ́n bà sí ẹ̀gbẹ́ ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò fò ju igbọnwọ meji lọ sílẹ̀, wọ́n wà ní ẹ̀yìn ibùdó káàkiri ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan.

32. Àwọn eniyan náà kó ẹyẹ ní ọ̀sán ati ní òru, ẹni tí ó kó kéré jù ni ó kó òṣùnwọ̀n homeri mẹ́wàá. Wọ́n sì sá wọn sílẹ̀ yí ibùdó wọn ká.

33. Nígbà tí wọn ń jẹ ẹran náà, ibinu OLUWA ru sí wọn, ó sì mú kí àjàkálẹ̀ àrùn jà láàrin wọn.

34. Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Kiburotu Hataafa, èyí tí ó túmọ̀ sí ibojì ojúkòkòrò, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n sin òkú àwọn tí wọ́n ṣe ojúkòkòrò ẹran sí.

35. Àwọn eniyan náà sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí Haserotu, wọ́n sì pàgọ́ wọn sibẹ.

Ka pipe ipin Nọmba 11