Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 10:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nígbà tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn ọmọ Israẹli jọ ẹ óo máa fọn fèrè, ṣugbọn kò ní jẹ́ ti ìdágìrì.

8. Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni ni yóo máa fọn fèrè náà.“Fèrè yìí yóo sì jẹ́ ìlànà fún ìrandíran yín.

9. Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

10. Ẹ óo máa fọn àwọn fèrè náà ní ọjọ́ ayọ̀, ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín ati ní ọjọ́ kinni oṣù. Ẹ óo máa fọn wọ́n nígbà tí ẹ bá mú ọrẹ ẹbọ sísun ati ọrẹ ẹbọ alaafia yín wá fún Ọlọrun. Yóo jẹ́ àmì ìrántí fun yín níwájú Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

11. Ní ogúnjọ́ oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, ìkùukùu tí ó wà ní orí ibi mímọ́ gbéra sókè.

12. Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani.

Ka pipe ipin Nọmba 10