Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 10:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Fi fadaka tí wọ́n fi òòlù lù ṣe fèrè meji fún pípe àwọn ọmọ Israẹli jọ ati títú ibùdó palẹ̀.

3. Nígbà tí àwọn afọnfèrè bá fọn fèrè mejeeji, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá sọ́dọ̀ rẹ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

4. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé fèrè kan ni wọ́n fọn, àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli nìkan ni yóo wá sọ́dọ̀ rẹ.

5. Nígbà tí ẹ bá kọ́ fọn fèrè ìdágìrì, àwọn tí wọ́n pa àgọ́ sí ìhà ìlà oòrùn Àgọ́ yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú.

6. Bí ẹ bá fọn fèrè ìdágìrì lẹẹkeji, àwọn tí wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Ìgbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́ tẹ̀síwájú ni kí ẹ máa fọn fèrè ìdágìrì.

7. Nígbà tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn ọmọ Israẹli jọ ẹ óo máa fọn fèrè, ṣugbọn kò ní jẹ́ ti ìdágìrì.

8. Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni ni yóo máa fọn fèrè náà.“Fèrè yìí yóo sì jẹ́ ìlànà fún ìrandíran yín.

9. Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

Ka pipe ipin Nọmba 10