Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 10:18-32 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Reubẹni ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni olórí wọn.

19. Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni olórí ẹ̀yà Simeoni.

20. Olórí ẹ̀yà Gadi sì ni Eliasafu ọmọ Deueli.

21. Lẹ́yìn wọn ni àwọn ọmọ Kohati tí wọ́n ru àwọn ohun èlò mímọ́ tó ṣí. Èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari rí ààyè láti pa Àgọ́ Àjọ náà kí àwọn ọmọ Kohati tó dé.

22. Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Efuraimu ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Eliṣama ọmọ Amihudu ni olórí wọn.

23. Gamalieli ọmọ Pedasuri ni olórí ẹ̀yà Manase.

24. Olórí ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni Abidani ọmọ Gideoni.

25. Ní ìparí, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Dani ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni olórí wọn.

26. Pagieli ọmọ Okirani ni olórí ẹ̀yà Aṣeri.

27. Olórí ẹ̀yà Nafutali sì ni Ahira ọmọ Enani.

28. Bẹ́ẹ̀ ni ètò ìrìn àjò àwọn ọmọ Israẹli rí nígbà tí wọ́n ṣí kúrò ní ibùdó wọn.

29. Mose sọ fún Hobabu ọmọ Reueli, baba iyawo rẹ̀, ará Midiani, pé: “Àwa ń lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti ṣe ìlérí láti fún wa, máa bá wa kálọ, a óo sì ṣe ọ́ dáradára, nítorí OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun fún Israẹli.”

30. Ṣugbọn Hobabu dá a lóhùn pé: “Rárá o, n óo pada sí ilẹ̀ mi ati sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi.”

31. Mose sì wí pé: “Jọ̀wọ́ má fi wá sílẹ̀, nítorí pé o mọ aṣálẹ̀ yìí dáradára, o sì lè máa darí wa sí ibi tí ó yẹ kí á pa àgọ́ wa sí.

32. Bí o bá bá wa lọ, OLUWA yóo fún ìwọ náà ninu ibukun tí ó bá fún wa.”

Ka pipe ipin Nọmba 10