Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 1:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Isakari.

9. Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Sebuluni.

10. Ninu àwọn ọmọ Josẹfu, Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli ọmọ Pedasuri ni yóo sì jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Manase.

11. Abidani ọmọ Gideoni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini.

12. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Dani.

13. Pagieli ọmọ Okirani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Aṣeri.

14. Eliasafu ọmọ Deueli ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Gadi.

15. Ahira ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Nafutali.

16. Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn.

17. Mose ati Aaroni pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní ọjọ́ kinni oṣù keji,

18. pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé.

19. Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọmba 1