Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 1:42-48 BIBELI MIMỌ (BM)

42. Ninu ẹ̀yà Nafutali àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

43. jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).

44. Àwọn ni àwọn tí Mose ati Aaroni kà pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí mejila tí a yàn láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

45. Àròpọ̀ iye àwọn ọmọ Israẹli, ní ìdílé-ìdílé, láti ẹni ogún ọdún sókè, àwọn tí wọ́n lè lọ sójú ogun,

46. jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ eniyan o le egbejidinlogun ó dín aadọta (603,550).

47. Ṣugbọn wọn kò ka àwọn ọmọ Lefi mọ́ wọn,

48. nítorí pé OLUWA ti sọ fún Mose pé,

Ka pipe ipin Nọmba 1