Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 8:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Bani, Ṣerebaya, Jamini, Akubu, Ṣabetai, Hodaya, Maaseaya, Kelita, Asaraya, Josabadi, Hanani, ati Pelaaya ni wọ́n ń túmọ̀ àwọn òfin náà tí wọ́n sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan wọn, gbogbo àwọn eniyan dúró ní ààyè wọn.

8. Wọ́n ka òfin Ọlọrun ninu ìwé náà ketekete, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan, ó sì yé wọn.

9. Nehemaya tí ó jẹ́ gomina, ati Ẹsira, alufaa ati akọ̀wé, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n kọ́ àwọn eniyan náà sọ fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ má banújẹ́ tabi kí ẹ sọkún.” Nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ń sọkún nígbà tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ inú òfin náà.

10. Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.”

11. Àwọn ọmọ Lefi rẹ àwọn eniyan náà lẹ́kún, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní, ẹ má bọkàn jẹ́.”

12. Gbogbo àwọn eniyan náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì fi oúnjẹ ati ohun mímu ranṣẹ sí àwọn eniyan wọn, wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá nítorí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn.

13. Ní ọjọ́ keji, àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Ẹsira, akọ̀wé, kí ó lè la ọ̀rọ̀ òfin náà yé wọn.

14. Wọ́n rí i kà ninu òfin tí OLUWA fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ̀dún oṣù keje,

15. ati pé kí wọ́n kéde rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìlú wọn ati ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ lọ sí orí àwọn òkè, kí ẹ sì mú àwọn ẹ̀ka igi olifi wá, ati ti paini, ati ti mitili, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka àwọn igi mìíràn láti fi pàgọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀.”

Ka pipe ipin Nehemaya 8