Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.