Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:65-73 BIBELI MIMỌ (BM)

65. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fẹnu kan oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu yóo fi dé.

66. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa ó lé ojidinnirinwo (42,360),

67. yàtọ̀ sí àwọn iranṣẹkunrin wọn ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin lé ọọdunrun ati mẹtadinlogoji (7,337), wọ́n sì ní àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245) lọkunrin ati lobinrin. Àwọn ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736),

68. àwọn ìbaaka wọn jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245),

69. àwọn ràkúnmí wọn jẹ́ ojilenirinwo ó dín marun-un (435), àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sì jẹ́ ẹgbaata ó lé ọrindinlẹgbẹrin (6,720).

70. Àwọn olórí ní ìdílé kọ̀ọ̀kan kópa ninu iṣẹ́ náà. Gomina fi ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati aadọta àwo kòtò, ati ẹẹdẹgbẹta ó lé ọgbọ̀n (530) ẹ̀wù alufaa sí i.

71. Àwọn kan ninu àwọn baálé baálé fi ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati ẹgbọkanla (2,200) òṣùnwọ̀n mina fadaka.

72. Ohun tí àwọn eniyan yòókù fi sílẹ̀ ni ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n diramu wúrà ati ẹgbaa (2,000) ìwọ̀n mina fadaka ati aṣọ àwọn alufaa mẹtadinlaadọrin.

73. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ìlú Juda, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn aṣọ́bodè, ati àwọn akọrin, ati díẹ̀ lára àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kaluku ń gbé ìlú rẹ̀.Nígbà tí yóo fi di oṣù keje, àwọn ọmọ Israẹli ti wà ní àwọn ìlú wọn.

Ka pipe ipin Nehemaya 7