Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:38-52 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ ẹgbaaji ó dín aadọrin (3,930).

39. Àwọn alufaa nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jedaaya, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Jeṣua, jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973).

40. Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052).

41. Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247).

42. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017).

43. Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jeṣua, tí wọn ń jẹ́ Kadimieli, ní ìdílé Hodefa, jẹ́ mẹrinlelaadọrin.

44. Àwọn akọrin nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ mejidinlaadọjọ (148).

45. Àwọn olùṣọ́ ẹnubodè nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Ṣalumu, àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni, àwọn ọmọ Akubu, àwọn ọmọ Hatita, ati àwọn ọmọ Ṣobai. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogoje (138).

46. Àwọn iranṣẹ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa, ati àwọn ọmọ Tabaoti,

47. àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Sia, ati àwọn ọmọ Padoni,

48. àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba, ati àwọn ọmọ Ṣalimai,

49. àwọn ọmọ Hanani, àwọn ọmọ Gideli, ati àwọn ọmọ Gahari,

50. àwọn ọmọ Reaaya, àwọn ọmọ Resini, ati àwọn ọmọ Nekoda,

51. àwọn ọmọ Gasamu, àwọn ọmọ Usa, ati àwọn ọmọ Pasea,

52. àwọn ọmọ Besai, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefuṣesimu,

Ka pipe ipin Nehemaya 7