Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:34-46 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254).

35. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320).

36. Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345).

37. Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mọkanlelogun (721).

38. Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ ẹgbaaji ó dín aadọrin (3,930).

39. Àwọn alufaa nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jedaaya, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Jeṣua, jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973).

40. Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052).

41. Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247).

42. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017).

43. Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jeṣua, tí wọn ń jẹ́ Kadimieli, ní ìdílé Hodefa, jẹ́ mẹrinlelaadọrin.

44. Àwọn akọrin nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ mejidinlaadọjọ (148).

45. Àwọn olùṣọ́ ẹnubodè nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Ṣalumu, àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni, àwọn ọmọ Akubu, àwọn ọmọ Hatita, ati àwọn ọmọ Ṣobai. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogoje (138).

46. Àwọn iranṣẹ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa, ati àwọn ọmọ Tabaoti,

Ka pipe ipin Nehemaya 7