19. Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹtadinlaadọrin (2,067).
20. Àwọn ọmọ Adini jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín marun-un (655).
21. Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un.
22. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328).
23. Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324).
24. Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112).
25. Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un.
26. Àwọn ará Bẹtilẹhẹmu ati Netofa jẹ́ ọgọsan-an ó lé mẹjọ (188).
27. Àwọn ará Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128).
28. Àwọn ará Beti Asimafeti jẹ́ mejilelogoji.
29. Àwọn ará Kiriati Jearimu ati Kefira ati Beeroti jẹ́ ọtadinlẹgbẹrin ó lé mẹta (743).
30. Àwọn ará Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta lé mọkanlelogun (621).