Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 5:17-19 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Siwaju sí i, aadọjọ (150) àwọn Juu ati àwọn ìjòyè ni wọ́n ń jẹun lọ́dọ̀ mi, yàtọ̀ sí àwọn tíí máa wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.

18. Mààlúù kan ati aguntan mẹfa tí ó dára ni wọ́n ń bá mi pa lojumọ, wọn a tún máa bá mi pa ọpọlọpọ adìẹ. Ní ọjọ́ kẹwaa kẹwaa ni wọ́n máa ń tọ́jú ọpọlọpọ waini sinu awọ fún mi. Sibẹsibẹ, n kò bèèrè owó oúnjẹ tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ gomina, nítorí pé ara tí ń ni àwọn eniyan pupọ jù.

19. Áà! Ọlọrun mi, ranti mi sí rere nítorí gbogbo rere tí mo ti ṣe fún àwọn eniyan wọnyi.

Ka pipe ipin Nehemaya 5