Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 12:25-32 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Matanaya, Bakibukaya ati Ọbadaya, ati Meṣulamu, Talimoni, ati Akubu ni wọ́n jẹ́ olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà bodè tí wọn ń ṣọ́ àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ẹnubodè.

26. Gbogbo nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati nígbà ayé Nehemaya, gomina, ati Ẹsira Alufaa ati akọ̀wé.

27. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu.

28. Àwọn ìdílé akọrin bá kó ara wọn jọ láti gbogbo agbègbè Jerusalẹmu ati láti àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká Netofati,

29. bákan náà ni láti Betigiligali ati láti ẹkùn Geba, ati Asimafeti, nítorí pé àwọn akọrin kọ́ ìletò fún ara wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.

30. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àwọn eniyan ati àwọn bodè ati odi ìlú náà.

31. Mo bá kó àwọn ìjòyè Juda lọ sórí odi náà, mo sì yan ọ̀wọ́ meji pataki tí wọ́n ṣe ìdúpẹ́ tí wọ́n sì tò kọjá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.Àwọn kan tò lọ ní apá ọ̀tún odi náà lọ sí Ẹnubodè Ààtàn,

32. lẹ́yìn náà, Hoṣaaya ati ìdajì àwọn ìjòyè Juda tẹ̀lé wọn,

Ka pipe ipin Nehemaya 12