Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 12:19-27 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Jehonatani ni baálé ní ìdílé Ṣemaaya,Matenai ni baálé ní ìdílé Joiaribu,

20. Usi ni baálé ní ìdílé Jedaaya,Kalai ni baálé ní ìdílé Salai,

21. Eberi ni baálé ní ìdílé Amoku,Haṣabaya ni baálé ní ìdílé Hilikaya,Netaneli ni baálé ní ìdílé Jedaaya.

22. Nígbà ayé Eliaṣibu ati Joiada, Johanani ati Jadua, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ṣe àkọsílẹ̀ àwọn baálé baálé ní ìdílé baba wọn títí di àkókò ìjọba Dariusi ọba Pasia.

23. Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn baálé baálé ninu àwọn ọmọ Lefi títí di ìgbà ayé Johanani ọmọ Eliaṣibu wà ninu ìwé Kronika.

24. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aṣiwaju ninu àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Haṣabaya, Ṣerebaya, ati Joṣua ọmọ Kadimieli pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró kọjú sí ara wọn, àwọn ìhà mejeeji yin Ọlọrun lógo wọ́n sì dúpẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi, eniyan Ọlọrun fi lélẹ̀.

25. Matanaya, Bakibukaya ati Ọbadaya, ati Meṣulamu, Talimoni, ati Akubu ni wọ́n jẹ́ olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà bodè tí wọn ń ṣọ́ àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ẹnubodè.

26. Gbogbo nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati nígbà ayé Nehemaya, gomina, ati Ẹsira Alufaa ati akọ̀wé.

27. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu.

Ka pipe ipin Nehemaya 12