Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 11:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Gabai ati Salai. Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bẹnjamini wá jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mejidinlọgbọn (928).

9. Joẹli ọmọ Sikiri ni alabojuto wọn, Juda ọmọ Hasenua ni igbákejì rẹ̀ ní ìlú náà.

10. Àwọn alufaa ni: Jedaaya ọmọ Joiaribu ati Jakini;

11. Seraaya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí ilé Ọlọrun,

12. ati àwọn arakunrin wọn tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ ilé náà, wọ́n jẹ́ ẹgbẹrin lé mejilelogun (822).Adaya ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelalaya, ọmọ Amisi, ọmọ Sakaraya, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija,

13. ati àwọn arakunrin rẹ̀, àwọn baálé baálé lápapọ̀ jẹ́ ojilerugba ó lé meji (242).Amaṣisai, ọmọ Asareli, ọmọ Asai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Imeri,

14. ati àwọn arakunrin rẹ̀. Alágbára ati akọni eniyan ni wọ́n, wọ́n jẹ́ mejidinlaadoje (128). Sabidieli ọmọ Hagedolimu ni alabojuto wọn.

15. Àwọn ọmọ Lefi ni: Ṣemaaya, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Bunni.

Ka pipe ipin Nehemaya 11