Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 11:27-36 BIBELI MIMỌ (BM)

27. ní Hasariṣuali ati ní Beeriṣeba, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

28. ní Sikilagi ati ní Mekona ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

29. ní Enrimoni, ní Sora, ati ní Jarimutu,

30. ní Sanoa, ati Adulamu, ati àwọn ìletò àyíká wọn, ní Lakiṣi ati àwọn ìgbèríko rẹ̀, ati ní Aseka ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀. Wọ́n pàgọ́ láti Beeriṣeba títí dé àfonífojì Hinomu.

31. Àwọn eniyan Bẹnjamini náà ń gbé Geba lọ sókè, títí dé Mikimaṣi, Aija, Bẹtẹli, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

32. ní Anatoti,

33. Nobu, Ananaya ati Hasori, ní Rama ati Gitaimu,

34. ní Hadidi, Seboimu, ati Nebalati,

35. ní Lodi, ati Ono, àfonífojì àwọn oníṣọ̀nà.

36. A sì pa àwọn ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Lefi kan ní Juda pọ̀ mọ́ ti àwọn ọmọ Bẹnjamini.

Ka pipe ipin Nehemaya 11