Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 11:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ṣabetai ati Josabadi, láàrin àwọn olórí ọmọ Lefi, ni wọ́n ń bojútó àwọn iṣẹ́ òde ilé Ọlọrun.

17. Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sabidi, ọmọ Asafu, ni olórí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdúpẹ́ ninu adura, ati Bakibukaya tí ó jẹ́ igbákejì ninu àwọn arakunrin rẹ̀, Abuda, ọmọ Ṣamua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

18. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284).

19. Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172).

20. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà ní àwọn ìlú Juda, kaluku sì ń gbé orí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

21. Ṣugbọn àwọn iranṣẹ tẹmpili ń gbé ilẹ̀ Ofeli, Siha ati Giṣipa sì ni olórí wọn.

22. Usi ni alabojuto àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Usi yìí jẹ́ ọmọ Bani, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mika, lára àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin. Òun ni olùdarí ìsìn ninu ilé Ọlọrun.

23. Ọba ti fi àṣẹ lélẹ̀ nípa iṣẹ́ àwọn akọrin, ètò sì wà fún ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa fún wọn lojoojumọ.

24. Petahaya ọmọ Meṣesabeli, lára àwọn ọmọ Sera, ọmọ Juda, ni aṣojú ọba nípa gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli.

25. Ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìletò ati àwọn pápá oko wọn, àwọn ará Juda kan ń gbé Kiriati Ariba ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, àwọn mìíràn sì ń gbé Diboni ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jekabuseeli ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

26. ati ní Jeṣua, ati ní Molada, ati ní Betipeleti,

27. ní Hasariṣuali ati ní Beeriṣeba, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

Ka pipe ipin Nehemaya 11