Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 11:15-19 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Àwọn ọmọ Lefi ni: Ṣemaaya, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Bunni.

16. Ṣabetai ati Josabadi, láàrin àwọn olórí ọmọ Lefi, ni wọ́n ń bojútó àwọn iṣẹ́ òde ilé Ọlọrun.

17. Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sabidi, ọmọ Asafu, ni olórí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdúpẹ́ ninu adura, ati Bakibukaya tí ó jẹ́ igbákejì ninu àwọn arakunrin rẹ̀, Abuda, ọmọ Ṣamua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

18. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284).

19. Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172).

Ka pipe ipin Nehemaya 11