Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 1:8-11 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ranti ìlérí tí o ṣe fún Mose, iranṣẹ rẹ, pé, ‘Bí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́, n óo fọn yín káàkiri sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

9. ṣugbọn tí ẹ bá pada sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa òfin mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀lé e, bí ẹ tilẹ̀ fọ́nká lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, n óo ṣà yín jọ, n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti yàn pé ẹ óo ti máa sìn mí kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀.’

10. “Iranṣẹ rẹ ni wọ́n, eniyan rẹ sì ni wọ́n, àwọn tí o ti fi ipá ati agbára ọwọ́ rẹ rà pada.

11. OLUWA, tẹ́tí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mo bẹ̀rù orúkọ rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, kí n sì rí ojurere ọba.”Èmi ni agbọ́tí ọba ní àkókò náà.

Ka pipe ipin Nehemaya 1