Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nahumu 3:17-19 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àwọn olórí yín dàbí tata, àwọn akọ̀wé yín sì dàbí ọ̀wọ́ eṣú, tíí bà sórí odi nígbà òtútù, nígbà tí oòrùn bá yọ wọn a fò lọ; kò sì ní sí ẹni tí yóo mọ ibi tí wọ́n lọ.

18. Àwọn olùṣọ́ rẹ ń sùn, ìwọ ọba Asiria, àwọn ọlọ́lá rẹ sì ń tòògbé; Àwọn eniyan rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè, láìsí ẹni tí yóo gbá wọn jọ.

19. Kò sí ẹni tí yóo wo ọgbẹ́ rẹ sàn nítorí egbò rẹ pọ̀. Àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn rẹ yóo pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí kò sí ẹni tí kò tíì faragbá ninu ìwà burúkú rẹ.

Ka pipe ipin Nahumu 3