Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nahumu 3:13-17 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dàbí obinrin! Gbogbo ẹnubodè rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná sì ti jó gbogbo ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ.

14. Ẹ pọn omi sílẹ̀ de àkókò tí ogun yóo dótì yín, ẹ ṣe ibi ààbò yín kí ó lágbára; ẹ lọ sí ibi ilẹ̀ alámọ̀, ẹ gún amọ̀, kí ẹ fi ṣe bíríkì!

15. Ibẹ̀ ni iná yóo ti jó yín run, idà yóo pa yín lọ bí eṣú. Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ pọ̀ bí eṣú!

16. O ti wá kún àwọn oníṣòwò rẹ, wọ́n sì pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ! Ṣugbọn wọ́n ti na ìyẹ́ wọn bí eṣú, wọ́n sì fò lọ.

17. Àwọn olórí yín dàbí tata, àwọn akọ̀wé yín sì dàbí ọ̀wọ́ eṣú, tíí bà sórí odi nígbà òtútù, nígbà tí oòrùn bá yọ wọn a fò lọ; kò sì ní sí ẹni tí yóo mọ ibi tí wọ́n lọ.

Ka pipe ipin Nahumu 3