Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 7:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo gbé! Nítorí pé, mo dàbí ìgbà tí wọn ti kórè èso àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tán, tí wọ́n ti ká èso àjàrà tán; tí kò sí èso àjàrà mọ́ fún jíjẹ, tí kò sì sí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́ tí mo fẹ́ràn mọ́.

2. Olóòótọ́ ti tán lórí ilẹ̀ ayé, kò sí olódodo mọ́ láàrin àwọn eniyan; gbogbo wọn ń wá ọ̀nà ìpànìyàn, olukuluku ń fi àwọ̀n dọdẹ arakunrin rẹ̀.

3. Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi í ṣe dáradára; àwọn ìjòyè ati àwọn onídàájọ́ wọn ń bèèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eniyan ńlá ń sọ èrò burúkú tí ó wà lọ́kàn wọn jáde; wọ́n sì ń pa ìmọ̀ wọn pọ̀.

4. Ẹni tí ó sàn jùlọ ninu wọn dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ láàrin wọn sì dàbí ẹ̀gún ọ̀gàn.Ọjọ́ ìjìyà tí àwọn wolii wọn kéde ti dé; ìdàrúdàpọ̀ wọn sì ti kù sí dẹ̀dẹ̀.

5. Má gbára lé aládùúgbò rẹ, má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rẹ́; ṣọ́ra nípa ohun tí o óo máa bá iyawo rẹ sọ.

6. Nítorí ọmọkunrin ń tàbùkù baba rẹ̀, ọmọbinrin sì ń dìde sí ìyá rẹ̀, iyawo ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ará ilé ẹni sì ni ọ̀tá ẹni.

7. Ṣugbọn ní tèmi, n óo máa wo ojú OLUWA, n óo dúró de Ọlọrun ìgbàlà mi; Ọlọrun mi yóo sì gbọ́ tèmi.

Ka pipe ipin Mika 7