Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 5:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ati bí ọ̀wààrà òjò lára koríko, tí kò ti ọwọ́ eniyan wá.

8. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.

9. O óo lágbára ju àwọn ọ̀tá rẹ lọ, a óo sì pa wọ́n run.

10. Ní ọjọ́ náà, n óo pa àwọn ẹṣin yín run, n óo sì run gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun yín.

11. N óo pa àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ yín run, n óo sì wó ibi ààbò yín lulẹ̀.

12. N óo pa àwọn oṣó run ní ilẹ̀ yín, ẹ kò sì ní ní aláfọ̀ṣẹ kankan mọ́.

13. N óo run àwọn ère ati àwọn òpó oriṣa yín, ẹ kò sì ní máa bọ iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́.

14. N óo run àwọn ère oriṣa Aṣera láàrin yín, n óo sì run àwọn ìlú yín.

15. Ninu ibinu ati ìrúnú mi, n óo gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò pa àṣẹ mi mọ́.

Ka pipe ipin Mika 5